Kí ni korona àti kí ni mo lè ṣe nípa rẹ?

Fairọsi korona tàbí korona je kòkòrò kékeré (ó kéré lati rí pẹlú ojú lásán) èyí ti o le tàn kálẹ̀ ti o si lé fá àisàn fún ènìyàn. Korona ń fà àmì bíi àrùn gágá olòtútù bíi ikọ gbígbẹ, kéèyan má lè mí délẹ̀ dáadáa, ibà àti ara riro. Korona sábà máa ń nípa lórí ẹ̀yà ara fún mímí. Nígbà tí ọpọ àléébù kò léwu, eléyìí lè fà ẹgbẹ didun (alebu líle tí ẹ̀dọ̀fóró), eléyìí sí lewu ni ọ̀ràn lílekoko.

Ẹnikẹni lé ní korona. Àwọn àgbàlagbà àti àwọn ti o bá ní àrùn mìíràn, àpẹẹrẹ bí àrùn àìlèmí dáadáa, jẹdọjẹdọ tàbí ìtó ṣùga wá ní ewu pupọ láti ni ewú àléébù rẹ.

Korona tán kalẹ láti ọ̀dọ̀ alárùn nínú ẹ̀kán tí wọn ba mi, wúkọ́ tàbí sin sì ènìyàn lára, orí nǹkan tàbí sí orí oúnjẹ. Ó ń wọ inú àrà láti ẹnu, imu àti ojú. Tí ó bá tí wá nínú ara, yìí ó bẹ̀rẹ̀ si ní dí pupọ a wá tán kalẹ sí àwọn ibòmíràn. Korona le wa lára fún ọjọ mẹ́rìnlá ki èèyàn tó bẹ̀rẹ̀ si ni rí àmì àìsàn. Nítorí náà èèyàn le ni korona ki ọ ma mọ, wọn sí má fún àwọn ẹlòmíràn ní fáírọ́ọ̀sì náà.

Oògùn agbógunti kòkòrò àrùn tàbí oògùn ìbílẹ̀ kó lè pá korona. Ohun kan ṣoṣo tí a fi le gbógun ti ni yiya go fún àti fífọ ọwọ lóore koore.

Lati má nìí àrùn náà, fọ ọwọ pẹlu ọṣẹ àti omi. Ṣé eléyìí, pàápàá ti ọwọ ko ba dọti. Fọ dáadáa lábẹ́ omi to nyọ fún ogún ìṣẹ́jú wínníwínní pẹlu ọṣẹ, ríi dájú pé o fọ aarin àwọn ika ọwọ titi dé ọwọ àti ọrùn ọwọ. Fífọ ọwọ pẹ̀lú ọṣẹ àti omi máa pá fáírọ́ọ̀sì tó lè wá ni ọwọ rẹ. Máa fọ ọwọ ki o to se oúnjẹ, bi o ṣe ń se lọ́wọ́ àti bi o ba ti se tán, lẹ́yìn tí ó bá ti lo ilé igbọnsẹ, ki o to jẹun, ti o bá ń tọju aláìsàn, nígbàtí o bá tọju ẹranko tan, tabi ìgbé ẹran, lẹ́yìn ti o bá wú kọ, sìn tabi fọn imú.

Máṣe fi ọwọ kàn ojú, imú tàbí ẹnu lai kọkọ fọ ọwọ. Ọwọ máa ń kán ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun o sì lè kan fáírọ́ọ̀si. Lọgan ti o bá ti kan fáírọ́ọ̀sì, ọwọ le ko ran ojú, imú àti ẹnu. Láti ibẹ, fáírọ́ọ̀sì náà lé wọ ara rẹ lọ ó si lè fa àisàn.

O ṣe pàtàkì gidigan láti yẹra fún sísunmọ eniyan ti o bá ní iba tabi ikọ tabi àìsàn ailemi dáadáa mìíràn gbogbo. Nígbà tí a ba n wù kọ tabi sìn, má bo ẹnu àti imú rẹ pẹlu igunpa rẹ tàbí bébà anùdọ̀tí nígbà gbogbo. Kí ó sì sọ bébà anùdọ̀tí náà nu lẹ́sẹkẹsẹ. Má ṣe tutọ ni gbangba.

Ni ìwọń bi ẹsẹ mẹta láàrín ìwọ àti ẹni tó bá nwuko tàbí sìn. Máṣe sunmọ enitó ba ni ìbá tàbí ikọ.

Ti o bá nílò láti tọju enitó ni ìbá, ikọ àti ti ko lémi dáadáa, máṣe gbàgbé láti wọ iboju tàbí ibara ati ni pataki julọ, ímọtótó ọwọ.

Lati má ni korona, ó sán láti yàgò fún sísunmọ àwọn ẹlòmíràn. A lè ko korona àti àwọn fáírọ́ọ̀sì mìíràn nípa gbígba ọwọ, ka tún wà fí ọwọ náà kan ojú, imú tàbí ẹnu. Nítorí náà, tí a bá pàdé ènìyàn, e ma gba wọn lọwọ, ìfọwọ́gbánimọ́ra tabi fẹnukẹnu. Jù ọwọ sí àwọn èèyàn, pẹ̀lú mimi orí tàbí ki ó tẹrí rẹ bá ti o bá fẹ́ ki àwọn èèyàn. Tí o bá gburo korona ni àdúgbò rẹ, duro sílè ki o ma bàa ni ibaṣepọ pẹ̀lú ènìyàn.

Dúró sí ilé ti ọ bá rí wípé ara ẹ ń ṣe ẹ bákan, ibá jẹ ifori lásán, imu nṣe ikun diẹ titi ti waa fi ni àlàáfíà. Tí ó bá ń sìn, ní ikọ gbígbẹ, ní ìnira láti mi àti iba, lọ gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn kíákíá nítorí èyí lé jẹ́ nítorí pé àkóràn àrùn ailemi dáadáa tàbí ọ̀ràn mìíràn tó lé.

Ìgbàgbọ́ èké àti àhesọ nípa korona lè léwu gan-an ó sì lé pá àwọn ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, mímu ọṣẹ ìṣídọ̀tí àti ọtí yóò pa yín lára dipo didena korona. Kódà ìsọfúnni tí o rí gbà látọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ àti ìbátan tímọ́tímọ́ lè jẹ nǹkan ti kò tọ̀nà tàbí tó léwu. Àbá ìlera pípéye látọ̀dọ̀ àwọn alábòójútó ètò ìlera ládùúgbò rẹ nìkan ni ko tẹ̀ lé.

Ó lè ṣeranlọwọ láti gbógunti korona nípa títan ọ̀rọ̀ yìí kalẹ. Jọ̀wọ́ ṣàjọpín rẹ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ àti ìdílé, ó dára kí ó jẹ́ lílo ìpèsè àtẹ̀jíṣẹ́ bí WhatsApp.

Audiopedia lo gbé ohùn tó wà nínú ìwé yìí kalẹ, iṣẹ́ àkànṣe àgbáyé láti jẹ kí ìmọ̀ ìlera ṣeégbọ́. Túbọ̀ lọ kọ́ nípa rẹ lórí www.audiopedia.org.